Yoruba

Àjọ NAPTIP Gùnlé Ètò Ìdánilẹ́kọ Fáwọn Òsìsẹ́ Rẹ̀ Láti Gbógun Ti Ìwà Ìfinisòwò Lọ́nà Àitọ́

Àjọ tón gbógun ti fífi èyàn sòwò lọ́nà àitọ́, ti bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ fún àwọn òsìsẹ́ nípinlẹ̀ lórí gbígbógun ti gbígbé àwọn èyàn kúrò lórílẹ̀èdè yíì lọ́nà àitọ́.

Olùdarí àgbà fájọ ọ̀hún Arábìnrin Julie Okah-Donli ló sọ eléyíì di mímọ̀ lásìkò ìdánilẹ́kọ tó wáyé nílu Èkó, tó sì sàpèjúwe ìdásílẹ̀ ikọ̀ òsìsẹ́ tí yóò máà gbógun ti fífi èyàn sòwò gẹ́gẹ́bí èyí tó se àtẹ́wọ́gbà.

Óní àwọn akópa tí wọ́n se ìdánilẹ́kọ fún ló wá láti ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti Ọ̀yọ́.

Arábìnrin Okah-Donli wá sáláyé pé, ikọ̀ náà jẹ́ ara ìgbésẹ̀ tájọ ọ̀hún gbé kalẹ̀ láti mú kíwà ìbàjẹ́ yi dópin sọ pé ìpèníjà tájọ náà ńkojú ki ń se kekére pẹ̀lú àfikún pé àwọn ìlànà àti ètò tuntun ni wọ́n gbọ́dọ̀ lò láti jẹ́ kíwà ìbàjẹ́ ọ̀hún di àfìsẹ́yìn fégún ńfisọ.

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *