Yoruba

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkìtì Ti S’àwárí Àwọn Ayédèrú Òsìsẹ́ Tó Lé L’ọdunrun Níye

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkìtì ti sọ pé ìpínlẹ̀ náà ńpàdánù owó tó jẹ́ milliọnu lọ́nà ogún naira lórí àwọn ayédèrú òsìsẹ́ tó lé ọdurun níye láwọn ìjọba ìbílẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀hún.

Nínú àbọ̀ ìwádi èyí tígbìmọ̀ tón tọpinpin ìsẹ̀lẹ̀ náà tíjọba gbá kalẹ̀ fisíta.

Nígbà tón gbé àbọ̀ ọ̀hún fún Gómìnà Kayọde Fayẹmi nílu Adó-Èkìtì, alákoso fọ́rọ̀ tóníse pẹ̀lú ìjọba ìbílẹ̀ àti ìdàgbàsókè agbègbè, ọ̀jọ̀gbọ́n Adio Fọlayan, sọpé akápò àgbà ni wọ́n ti pa lásẹ fún láti dáwọ́ sísan owó osù dúró fún àwọn ayédèrú òsìsẹ́ wọ̀nyí.

Ọjọgbọn Fọlayan se lálàyé pé iye àwọn òsìsẹ́ yi ló jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ́ta ólé méjì níye.

Ó sọ síwájú pé, ìgbìmọ̀ náà gba níyànjú pé kí wọ́n yọ owó tí wọ́n gbà lọ́nà àitọ́ yi kúrò nínú owó ìfẹ̀yìntì wọn, bákanà kí wọ́n mójú wọn balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn líluni ní jìbìtì.

Nígbà tón gba àbọ̀ ọ̀hún, Gómìnà Kayọde Fayẹmi dúpẹ́ lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ fún isẹ́ takuntakun tí wọ́n se tó sì sèlérí pé wọ́n yo gbé ìgbésẹ̀ kọ́mọ́nkìa lórí rẹ̀.

Tọpe Bamidele/Ọlọ́ládé Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *