Káabo tó péye le wà láwọn ibùdó ìfinimọ́lé fáwọn àgùnbánirọ̀ yíká orílẹ̀èdè yí, àjọ tón gbógunti ìtànkẹ́lẹ̀ àrùn ti sọpé gbogbo àwọn tó fẹ́ sìnrúlu ni wọ́n yo se àyẹ̀wò fun nípa irinsẹ́ tuntun fún síse àyẹ̀wò fún àrùn COVID-19.

Olùdarí àjọ náà Ọ̀mọ̀wé Chukwe Ihekweazu ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò tón jíròrò papọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ tó jẹ́ tìjọba àpapọ̀ pẹ̀lú àtọ́kasí pé ó se pàtàkì láti mú kí àbò wà ní gbogbo ibùdó ìfinimọlé yíká ilẹ̀ yí.

Ó sọ síwájú pe, ìjọba ti se ìfilọ́lẹ̀ ìlànà láti fòpin sí ìtànkálẹ̀ yíká gbogbo ìpínlẹ̀, pẹ̀lú àtọ́kasí pé gbogbo ọ̀dọ́ tó nífẹ sí ìdánilẹ́kọ lórí ìtọ́jú ara ẹni ni wọ́n yò dálẹ̀kọ́.

Oluwakayode Banjọ/Ọlọ́ládé Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *