Yoruba

Ilé Ìfowópamọ́ Ró Àwọn Olùdókòwò L’ágbára N’ípinlẹ̀ Èkìtì

Bánki tón rísí àwọn ilésẹ́ olókowò, ọ̀hún ti satán láti pèsè owóya tí yo wọ billiọnu kan naira láti ró àwọn onísòwò lágbára nípinlẹ̀ Èkìtì.

Olùdarí àgbà fún ilé ìfowópamọ́ náà, nípinlẹ̀ Òndó àti Èkìtì, ọ̀gbẹ́ni Seyi Ashaolu ló jẹ́ kọ́rọ̀ yi di mímọ̀ nílu Adó-Èkìtì, tọ́kasi pé bánki náà setán láti yá àwọn olókowò àti ẹnìkọ̀kan tó fẹ́ dókowò papa lẹ́ka ìlera ìpèsè óujẹ ni wọn yo ni ànfàní láti yá owó.

Ó wá rọ àwọn alákoso, láti gbé ìlànà kalẹ̀, tí wọ́n yo fi gba àwọn owó tí wọ́n ti yá, lára àwọn onísòwò nípinlẹ̀ ọ̀hún padà.

Nínú ọ̀rọ̀ alákoso, ọ̀gbẹ́ni Muyiwa Olumilua gbóríyìn fún ilé ìfowópamọ́ tón rísí ìdókowò fún ìgbésẹ́ ìbásepọ̀ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Èkìtì, tó sì sọ̀rọ̀ ìdánilójú pé gbogbo àtìlẹyìn tó yẹ nìjọba yo gbe nípasẹ̀, ilésẹ́ tón rísí okòwò àti àwọn ilésẹ́ ńláńlá.

Bákanà ni ó bu ẹnu àtẹ́lu, báwọn tó gba owó ọ̀hún tẹ́lẹ̀ se kùnà láti san padà, tó sì sọpé èyí tí wọn gbé kalẹ̀ báyi ni wọ́n yo pin nípasẹ̀ àwọn ẹgbẹ́ alájẹsékù, kó lè rọrùn fún ìjọba láti gbáà padà.

Ọlọlade Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *