Onírurú ere-ídárayá ni yóò jẹ gbígbékalẹ̀ láwọn ilé-ìwé gbogbo tó ńbẹ nípinlẹ̀ lọ́dún tó ńbọ̀.

Olùránlọ́wọ́ pàtàkì sí Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ onímọ̀-ẹ̀rọ Seyi Makinde, fún ìdàgbàsókè ere-ìdárayá, ọ̀gbẹ́ni Oluwatobi Oyewumi sọ èyí lákokò tó ńbá ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn ere ìdárayá nílẹ̀ yíì SWAN ẹ̀ka tìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ sọ̀rọ̀.

Ó sàpèjúwe ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ọlọ́ra tólórun fi àwọn ọlọ́pọlọ pípé èdè jínki lẹ́ka ere ìdárayá, sàlàyé pé àgbékalẹ̀ ọ̀kan-òjọ̀kan àwọn ere ìdárayá ọ̀hún, kòní sàwárí ẹ̀bùn nìkan, àmọ́ yóò tun múwọn gòkè àgbà.

 Ọgbẹni Oyewumi sọpé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ere ìdárayá láwọn ẹsẹ̀ kùkú tófimọ́ tàwọn àkàndá ẹ̀dá yóò wáàyé lọ́dún tónbọ̀.

Ó sọdi mímọ̀ pé, àrùn covid-19 lósokunfà bẹ̀rẹ̀ ìdárayá àwọn àkàndá ẹ̀dá kose wáyé lọ́dún yíì pẹ̀lú àlàyé pé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ kòní fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ere ìdárayá àwọn àkàndá ẹ̀dá.

Fawọle/Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *