Bàbá kérésì ilésẹ́ Premier F.M 93.5 àti taúludùn F.M 99.1 yóò gunlẹ̀ bàagẹ̀ lọ́la òde yíì.

Àtẹ̀jáde kan, èyítí ìgbìmọ̀ ètò náà fisíta sọpé, àwọn ẹ̀bùn jàkàn-jàkàn ni yóò wà fáwọn òge wẹrẹ yíì lárin ago mẹ́wa òwúrọ̀ ságo márun ìrọ̀lẹ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan náirà péré.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún sèlérí pé, ìlànà àbò covid-19 tóòyẹ yọò wà fún àbò tópéye.

Ó sàlàyé pé bàbà kérésì alágbeká yóò wà kalẹ̀ láti sàbẹ̀wò sáwọn ilé ẹ̀kọ́ tóbá nífẹ síì.

Ìgbìmọ̀ ètò bàbá kérésì ọ̀hún fikun pé ànfàní wà fáwọn ọlọ́gà tó bá fẹ́ pàtẹ ọjà wọn ságbègbè ilésẹ́ Radio Nigeria dùgbẹ̀ àti Amuludun F.M Mọ́níyà lákokò pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún.

Abisọla Olurẹmi/Idogbe Elizabeth

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *