Yoruba

Ọga àgbà ilésẹ́ Radio Nigeria ẹkùn ìbàdàn bèrè fún gbígbé ìròyìn tí yóò fẹsẹ ìsòkan múlẹ̀

Olùdarí àgbà ilésẹ́ Radio Nigeria ìbàdàn, tó fẹ́ fẹ̀yìntì, Àhájì Mohammed Bello, ńfẹ́ káwọn oníròyìn máà wádi ohun gbogbo kí wọ́n sì ridájú pé, ìròyìn tó fìdí múlẹ̀ nìkan ni wọn ńgbé síta fún ìsọ̀kan ilẹ̀ yíì.

Àlhájì Bello ẹnitó sọ̀rọ̀ yíì lásìkò tó ńkopa lórí ètò ilésẹ́ Premier F.M lédè gẹssi THE STAGE, sàlàyé pàtàkì bóse yẹ káwọn oníròyìn ma sisẹ́ wọn bí isẹ́ pẹ̀lú ìwà ọmọlúàbí kí wọ́n sì máà jábọ̀ isẹ́ ìríjú àwọn adarí fáwọn èeyàn àwùjọ.

Nígbà tó ńsèpèjúwe ilésẹ́ Radio Nigeria gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ aráàlu, Àlhájì Bello sọ di mímọ̀ pé ilésẹ́ Radio Nigeria kòní káàrẹ láti máà fọnrere ìsọ̀kan ilẹ̀ yíì.

Àlhájì Bello ẹnitó kéde ìdásílẹ̀ ẹ̀ka ilésẹ́ Radio Nigeria titun méjì nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, rọ àwọn agbègbè táwọn ilésẹ́ náà wáà, ní ìjọba ìbílẹ̀ Surulere àti Ògbómọ̀sọ́ láti sàmúlò àwọn ilésẹ́ náà bótiyẹ.

Aminat Jibikẹ/Idogbe Elizabeth

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *