Àwọn ọmọkùnrin ọmọ ilé ìwé ìmọ̀ Sciensi tó wà ní Kankara tó lé ní ọọdunrun tí wọ́n jí gbé lọ, tí wọ́n gba òmìnira lálẹ́ àná ni wọ́n ti gúnlẹ̀ si ìpínlẹ̀ Kastina báyi.

Àwọn akẹ́kọ náà ni àwọn òsìsẹ́ aláabo sìn wọ olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Diẹ lára wọn ni wọ́n si wọ asọ ilé ìwé ni wọ́n kó sí gbọ̀ngàn ńlá nílé ìjọba níbi tí Gómìnà Aminu Masari ti tẹ́wọ́ gbà wọ́n.

Gómìnà náà wá sèlérí wípé àwọn ilé ìwé náà ni wọ́n yio fún ní àyẹ̀wò ìlera tó péye kí wọ́n tó darapọ̀ mọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn.

Gómìnà Masari ẹnití ó fìdí ìyọ̀nda àwọn akẹ́kọ tó jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹ́rìnlélógójì múlẹ̀.

Ó wá fikun wípé wọ ò san owó kankan láti da àwọn akẹ́kọ náà sílẹ̀.

Net/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *