Yoruba

Ìjọba Ìpińlẹ̀ Ògùn Déde Ìsinmi Ọdún Ọlọ́jọ́ Mẹ́rìnlá Fáwọn Òsìsẹ́

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti páà lásẹ fún àwọn òsìsẹ́ ìjọba ní ìpínlẹ̀ náà pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìsinmi ọdún kérésì àti ọdún tuntun láti òní ọjọ́ kẹrìnlélógún osù kejìlá títí di ọjọ́ kẹrin osù kínní ọdún tó ń bọ̀ nítorí bí àjàkálẹ̀ àrùn covid 19 se ń gbilẹ̀ lórílẹ̀èdè yí.

Akọ̀wé ìròyìn fún Gómìnà, Ọ̀gbẹ́ni Kunle Somọrin ló fojú ọ̀rọ̀ yí síta nílu Abẹokuta pẹ̀lú àlàyé wí pé Gómìnà Abiọdun ń fẹ́ káwọn òsìsẹ́ náà pa ara wọ́n mọ́ lásìkò ọdún, àti ètò àpéjọpọ̀ wọ ọdún tuntun pẹ̀lú àwọn ayẹyẹ min-in tí máà ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà Abiọdun tun páà lásẹ pé gbogbo èèyàn tí yóò bá wá ní ilé ìjọsìn kò gbọdọ̀ ju ìdá àadọ́ta lọ àti pé kò gbọdọ̀ sí àpéjọpọ̀ àayàn tí yóò tayọ àadọ́ta lẹ́ẹ̀kan soso nínú ayẹyẹ.

Ó tún tọ́ka si pé, gbogbo iléèwe tó wà ní ìpínlẹ̀ náà ló gbọdọ wà ní títìpa di ọjọ́ kejìlélógún osù kinni ọdún 2021, gómìnà tún se àfikún ẹ̀ pé ilé ọtí, àti ilé ijó, pẹ̀lú ibi ìgbafẹ́ gbogbo tó wà ní ìpínlẹ̀ náà gbọ́dọ̀ wà ní títìpa di ọjọ́ min ọjọ́re.

Fọlakẹmi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *