Yoruba

Iléesẹ́ Ọlọ́pa Kìlọ̀ Fáràalú Láti Kóra Wọn Níjanu Lásìkò Ọdún

Alákoso iléesẹ́ ọlọ́pa ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Nwachukwu Enwonwu ti sèkìlọ̀ fáwọn aráàlu pé kí wọ́n yàgò fún lílo òfin lọ́wọ́ ará wọn, léyi tó dàpè ní ìdájọ́ láàye ara ẹni.

Alákoso sípaya ọ̀rọ̀ yí nílu ìbàdàn pẹ̀lú àlàyé wí pé, káwọn èèyàn tètè máà fi ọ̀rọ̀ tó iléésẹ́ ọlọ́pa tó bá wà nítòsí létí nígbà yóòwù tí wọn bá mú ọ̀daràn, yàtọ̀ fún síse lelajọ láàye ara wọn, léyi tó jẹ́ pé wọ́n léè fìyà jẹ aláisẹ.

Ọgbẹni Enwonwu tún sèkìlọ̀ lórí yinyin ìbọn ọdún bíì banger àti àwọn ǹnkan a bú gbàmù min fún pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún.

Bákana náà ló tún korò ojú sí síse àpéjọpọ̀ òpópónà lásìkò àti lẹ́yìn ọdún.

Fọlakẹmi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *