Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonise Ìbàdàn tí bẹ̀rẹ̀ síní jiroro pẹ̀lú àwọn ádárì ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ ilé ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú ìrètí láti tètè yanjú ìyansẹ́lódì tó ń lọ lọ́wọ́.

Níbi ìpàdé tí Alága Ìgbìmò Aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kúnlé Akínyemí darí ni àwọn ọmọ ìgbìmò mẹ́tèeta yoku pé ṣe si àti àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà àti àwọn ádárì ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́.

Lásìkò iduna dura yí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínyemí béèrè fún àsìkò àti ìgbọ́rà-ẹni ye láti yanjú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀.

Ó wà rọ wọn láti jẹki àwọn akẹ́kọ̀ọ́ parí ìdánwò sáà kíní to ń lọ lọ́wọ́ kí wọn si àwọn ìloro ilé ẹ̀kẹ̀kọ náà láti lee jẹ́ kílílọ bí bọ̀ rọrùn.

Àwọn ẹgbẹ́ òsìsẹ́ náà fọwfọwosowopọ̀ lọ́nà àti tètè yanjú ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Lọ́jọ́ ąjé ọ̀sẹ̀ yi ni àwọn òsìsẹ́ ile ẹ̀kọ́ náà gunle ìyansẹ́lódì l’ori àìsan an owó oṣù tún tún.

Oluwayemisi Dadà

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *