Yoruba

Iko Amotekun Fokan Awon Eeyan Bale Lori Oro Aabo Agbegbe Ibarapa

Oga Agba fun iko alaabo Amotekun, Ajagunfeyinti  Olayinka Olayanju ti ni aheso oro ni iroyin to nlo kiri pe rukerudo n waye ni ijoba ibile aarin gbungbun ibarapa ati ariwa ibarapa nipinle yi.

Ajagbunfeyinti olayanju eniti o soro ye nilu Ibadan so wipe iko alaabo naa ti seto sile lati lee daabobo emi ati dukia awon eniyan.

O tun ni awon ohun ati fonran kan to nle kiri lori ero ayelujara je lati ko okan awon eniyan soke lasan ni to si le da wahala nile lagbegbe nbaa.

Gegebi o wi, awon agbe, ati awon are ilu agbegbe oun nba ise won lo laisi idaamu tabi ifoya Kankan.

Ajagunfeyinti olayanju fikun wipe iko alaabo naa ti nsewadi iroyin isekupani kan ti won ni o sele nibe to wa fid a awon olugbe ine loju wipe won nipe foju awon to huwa laabi oun han ati idi ti won fi se bee.

O wa ro awon eniyan iba lati tete maa foro ti iko amotekun ati awon ajo eleto abo lati bi won wa ninu isoro eyekeyi.

 Makinde/Dada                                

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *