Yoruba

NEMA gunle sise ato awon agbegbe to seese ko foju wina isele ekun omi

Ajo to n se kokari isele pajawiri nile yi, NEMA, ti gunle sise ato awon agbegbe to seese ko foju wina isele ekun omi lodun yi.

Oludari agba ajo NEMA nile yi, Ogbeni Muhammed Muhammed lo foju oro yi lede pelu alaye pe sise ato awon agbegbe to se e se kijamba ekun omi waye lodun 2021 lo waye nibamu pelu ikede ikilo ti ajo ti n wo sakun oju ojo fi lede.

Lati wa le dena ijamba buruku yi, Ogbeni Muhammed tenumo pe gbogbo igbese lati dena ijamba naa ni won yoo mu sa loogun.

Oga agba ajo NEMA salaye wi pe ipa ti ose ekun omi lee se fun emi ati dukia pelu awujo lo wa lowo igbaradi orileede lati dena ijamba naa loju ojo.

O wa soo di mimo pe, ajo NEMA yio ri daju pe ijoba apapo ipinle ati ibile pelu agbegbe kookan wa ni igbaradi lati koju ipenija naa.

Salaudeen 

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *