News Yoruba

Ajo NCDC Nfe Kawon Omo Ile Nigeria Si Ma Tele Ilana Abo Covid-19

Olori eka to nrisi isele pajawiri, lajo to n mojuto itankale aarun nile yi, dokita EVERISTUS ANIAKU, ti kesi awon eeyan ile yii lati ma kaare nidi igbese liana abo arun covid-19.

Dokita Aniaku, soro amoran yi lasiko eto idanieko fawon osise naa nipinle Eko.

O tokasi pe gbigba abere ajesara ko ni kawon eeyan dehin nidi pipa liana arun covid-19 mo, pelu atokasi pe opo orileede lo ti n koju arun covid 19 eleketa ati ekerin.

Ninu oro re, oludari ajo NCDC, leka idahun kiakiia eto ilera, Dokita JOHN Oladejo ni, Pataki idanileko ohun ni lati siseto bi adinku ati amojuto too peye yoo sewa fun itankale aarun nijoba apapo, ipile ati ibile.

Net/Idogbe