Yoruba

Ajo JAMB Seleri Eto to Pegede Fawon Akeko

Owo toto milionu mewa Naira ti won fe fi san owo awon osise pajawiri to ba ajo to n se idanwo asewole sile eko giga nile yi (JAMB) ni awon onijibiti ori ero ayelujara ti wo inu apo asuwon won.

Tori idi eyi, ajo naa soo di mimo pe won o ni se amulo ero ibanisoro alagbeka tabi oju opo ayelujara e-mail fun eto iforukosile idanwo naa.

Akowe agba ajo naa, Ojogbon Ishaq Oloyede to baa won oniroyin soro nilu Abuja salaye wi pe ilana tuntun ti won yio lo ni won yoo ti rii daju pe, enikeni ko mo nipa akeko to ba fe se idanwo yi lori ero ayelujara.

Ojogbon Oloyede salaye wi pe won onijibiti ori ero ayelujara ti kowo bo oju opo ajo naa to wa fawon osise pajawiri ti won si ko owo to wa fun won kuro lapo asunwon naa, amo o so asolaju pe won yoo ri owo naa gba pada.

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *