Aare Ile Igbimo Asofin agba, Ogbeni Ahmed Lawan ti sekilo fawon Gomina nipinle atawon miran to di ipo ase mu, tilu dibo yan, lati yago fun piparapo bere fun atunto nile yi.

Ilu Abuja ni Ogbeni Lawan ti soro yo, ro si ni ko ye ko je iru awon eeyan tilu dibo yan, ni won yoo ba nidi irufe iwayi.

Gegebi otiwi, oni ki won se atunto lawon ipinle kowa won, ki won to ma bere fun ti ijoba apapo.

Aare ile asofin tenumo pe, awon asaju yi lo ye ki won ri daju pe gbogbo onikojiko darapo mo eto isejoba ti yo le faye gba eni to ba ni nkan to le se lati mu kile yi goke agba lese laini idiwo.

O tokasi pe gbogbo eeyan nile yi lo ye ki won parapo laifi tie sin, asa tabi egbe oselu teni kookan di mu se, lati wojutu si gbogbo ipenija to n koju ile yi lapapo.

Aare ile asofin, Ogbeni Lawan, wa kesi gbogbo awon tilu dibo yan yika ema ijoba meteeta lati yago fun ikunsinu to le da togbodiyan sile tabil eyi to le fa ipinya.

Afonja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *