News Yoruba

Ilésẹ́ Àrẹ Ní Ìgbésẹ̀ Fífi Òpin Sí Kíkó Ẹranjẹ̀ Nítagbangba Táwọn Gómìnà Ní Gúsù Ilé Yí Fẹ Gùnlé Ni Kò Dára Tó

Ilésẹ́ àrẹ ti di ẹ̀bi ru ẹgbẹ́ àwọn Gómìnà ní gúsù ilẹ̀ yí pé wọ́n ti fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ fífi òpin sí kíkó ẹranjẹ̀ níta gbangba di ti ẹgbẹ́ òsèlú lásìkò ìpàdé tí to si léwu fún ètò àbò.

Nínú àtẹ̀jáde èyí tí amúgbájẹ́gbẹ fún àrẹ lórí ìròyìn àtọ̀rọ̀ tó kan arálu gbọ̀ngbọ̀n Mallam Garba shehu fisita lọ̀rọ̀ yí ti jẹyọ, pẹ̀lú àtọ́kasí pé ìgbésẹ̀ wọn lásìkò ìpàdé nílu Asaba nípinlẹ̀ Dẹlta, ló jẹ èyí ti kò bófin mu, tó sin dènà ẹ̀tọ́ àwọn èyàn nílẹ̀ Nàijírìa láti gbé àti dókowò níbi tó wùwọ́n, láifi ti ẹ̀yà tàbí ibi tí kówá ti sẹ́ẹ̀ wá se.

Gẹ́gẹ́bí àtẹ̀jáde náà ti se lálàyé àrẹ Muhammadu Buhari ti fọwọ́sí àwọn ìgbésẹ̀ àti ọ̀nà láti pinwọ́ àwọ́ọ̀ tó ń wáyé lárin àgbẹ̀ àti darandaran pẹ̀lú àfinkú pé ìgbésẹ̀ àwọn Gómìnà wọ̀nyí ni kò sọrọ ojútu sí gbọnmọgbọmọ rògbòdìyàn tón wáyé náà láti bi àimọye ọdún sẹ́yìn.

Àtẹ̀jáde náà wá kéde pé ìjọba àpapọ̀ yo bẹ̀rl sini sàmúlò ìgbésẹ̀ láti sàtúnse ibi tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti ma kẹ́ranjẹ̀, láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n bá ti fẹ́, bẹ̀rẹ̀ láti osù tón bọ̀.

Net/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *