Yoruba

Àarẹ Buhari síde ojú òpópónà ọkọ̀ ojúurin ìgbàlódé látìlú Èkó sílu Ìbàdàn oní kilometre mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ.

Àarẹ Buhari ti síde ojú òpó ọkọ̀ oju irin ìgbàlódé oní kolometre mẹ́tàdín lọ́gọ́jọ látilú Èkó sílu Ìbàdàn.

Nígbà tón báwọn ọmọ orílẹ̀dè yíì sọ̀rọ̀, àarẹ Buhari fi ìdùnú rẹ̀ hàn nípa bí àkànse isẹ́ ọkọ̀ ojúrin se jẹ́ sísí lásìkò ètò ìsèjọba rẹ̀.

Kò sài fi ìpinnu rl hàn láti sàtúnse ìlérí lórí gbogbo àwọn isẹ́ ìdàgbàsókè tón lọ yíká orílẹ̀dè yíì.

Lára àwọn èèyàn jànkànjànkàn tó péjú pésẹ̀ síbi ètò náà, latirí alákoso fétò ìròyìn àtàsà nílẹ̀ yíì Àlhájì Lai Muhammed, alákoso fọ́rọ̀ ọ̀dọ́ àti ìdàgbàsókè eré ìdárayá, ọ̀gbẹ́ni Sunday Dare, atakẹgbẹrẹ alákoso kejì fétò ìrìnà, Gbemisọla Saraki, àtadarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin kejì, ọ̀gbẹ́ni Fẹmi Gbajabiamila.

Àwọn tókù ni, alága fáperò àwọn Gómìnà títúnse Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì ọ̀mọ̀wé Kayọde Fayẹmi akẹgbẹ́ rẹ̀ láti ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti ọ̀yọ́ Babajide rẹ láti Seyi Makinde àti Dapọ Abiọdun.

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *