Gẹ́gẹ́bí ara ọ̀nà láti fòpin sí ètò àbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ ìbàràpá, adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ti gbé alùpùpù mẹdogun tuntun fáwọn ẹ̀sọ́ alábo tójẹ́ ọmọbíbí ilẹ̀ ìbàràpá.

Nígbà tón gbé àwọn alùpùpù náà fáwọn olórí agbègbè àti àwọn asíwájú ẹ̀sọ́ alábo lágbègbè nílesẹ́ ọlọ́pa tówà nílu Èrúwà, ọ̀gbẹ́ni Ogundoyin sọpé, ìgbésẹ̀ náà lówáyé láti mú àgbéga bá lílọ bíbọ̀ àwọn òsìsẹ́ alábo àmọ̀tẹ́kùn, OPC, àwọn ọdẹ tófimọ́ ikọ̀ vigilantee, láti mú àmú gbòrò dé bá isẹ́ wọn.

Nígbà tón fèsì, ọ̀gágba ilésẹ́ ọlọ́pa Èrúwà, ọ̀gbẹ́ni Peter Ugochucwu fi ẹ̀mí ìmore hàn sí olùdarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin, fún àtìlẹ́yìn tó se fún ẹ̀sọ́ alábo gbogbo.

Nígbà tón rọ àwọn èyàn láti túnbọ̀ sátìlẹyìn fún ilésẹ́ ọlọ́pa náà lọ́wọ́, sọwọ́ sí wọn, ọ̀gbẹ́ni Ugochuckwu wá fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé, ètò àbò yo tunbọ gbèrú si láwọn agbègbè náà.

Bákanà, alága, ìgbìmọ̀ àwọn olórí lágbègbè náà olooye Joseph Peluọla fi ìdùnú hàn lórí ìgbésẹ̀ olùdarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípa dídahun si ìbere àwọn èyàn lójú ọjọ́.

Láfẹ̀mọ̀júmọ́ ọjọ́ àikú Sunday tó kọjá, ni ìkọlù kan wáyé ní Ìgàngàn, lágbègbè ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Ìbàràpá nínú èyí tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ti sọnù tọ́kẹ àimọye dukia sì jóná tófimọ́ àfin Ashigangan tìlú Ìgàngàn.

Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *