Yoruba

Onímọ̀ Nípa Ètò Àwọn Ọmọdé Bèèrè Fún Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Lórí Àbò Àwọn Ògo Wẹẹrẹ

Ajáfẹ́tọ ọmọdé kan títúnse olùdarí àjọ Hope for Second chance Foundation, HOSEC, Arábìnrin Ibukunoluwa Otesile, ti bèèrè fún ìdí tó fi sepàtàkì fáwọn èèyàn àwùjọ láti máà sọ̀rọ̀jadé nígbà tí wọ́n bá ńfojú ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé gbolẹ̀.

Arábìnrin Otẹsile fìdí èyí múlẹ̀ lákokò tón bálesẹ́ wa sọ̀rọ̀ lórí àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ fún tọdún yíì.

Ó sàlàyé pé, ó ti sepàtàkì fún gbogbo àwọn èèyàn báyíì, láti jígìrì, gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ akin kan, fitako bíwọ́n se ń se àwọn ọmọdé nisekuse, sisẹ ìgbáyàwó fáwọn ọmọdé tọ́jọ́ orí wọn kò tónkan alákoso àwọn òbí kan, àti dídábẹ́ fáwọn ọmọbìnrin, lọ́nà àti dábòbò ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé.

Arábìnrin Ọtẹsile kò sài tún ké sáwọn ọmọdé láifi tèyíkèyí àbùdá se, láti máà wa lójú lala kan fi ń sọrí, lórí àbò ara wọn, kíwọ́n sì máà jábọ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ fọwọ́ kan wọ́n tàbí fẹ́ sewọ́n nísekúse fáwọn èèyàn tíwọ́n bá nígbàgbọ́ nínú wọn.

Ó wá sàpèjúwe àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ gẹ́gẹ́ bí kíkésí àwọn alásẹ tọ́rọkàn láti mọrọ ìgbáyégbádùn àwọn ògo wẹẹrẹ lọ́kunkúndùn.

Mosope Kehinde/Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *