Alakoso teleri foro ibara eni soro nileyi, Ogbeni Adebayo Shittu ti soo di mimo pe ipo ti eto eko de duro lorileede yi kii se ohun to boju mu.

Ogbeni Shittu sipaya oro yi lasiko eto ayajo awon ere nile Africa, eyi ti leese wa Premier FM, Ibadan se agbekale re.

Alakoso teleri naa, eni tii tun se baba ojo naa salaye wipe ijoba nilo lati mu eto eko lokun kundun, ki won lee pe ogo eto eko ile yi pada.

Ninu oro re, Adele Oludari agba ileese Radio Nigeria, Ibadan, Arabinring Bolanle Owoyemi tenumo igbiyanju ileese Radio Nigeria nipa ipolongo tako fifi omo loko ni mojesin, pelu iwa nabi ati jiji omo gbe.

Saaju ninu oro ikini kaabo, Oga Agba ileese, Premier FM, Iyaganku, Aderemi Omotoso benu ate lu bi iye awon ewe ti to lo sileewe nile Africa se n fojoojumo po si nile Africa, leyi to so po poju lawujo to wa laarin ojo ori odun mefa si odun mokanla.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *