Alamojuto eto iroyin, oro asa ati irin ajo afe nipinle Oyo Omowe Wasiu Olatunbosun ti fawon eeyan ipinle Oyo lokan bale wi pe gbogbo awon to wa nidi rogbodiyan to be sile lagbegbe Iwo Road nilu Ibadan ni won yio foju won lede faraye, ti won yio si foju wina ofin.

Alamojuto naa sipaya oro yi lasiko to n kopa lori eto ileese agbohunsafefe aladani kan nilu Ibadan.

Omowe Olatunbosun soodi mimo wipe awon agbofinro ti bere ise iwadi lori ohun to sokunfa rogbodiyan naa.

O salaye wi pe ijoba ko kawo gbera lori wahala naa ati pe gbogbo awon to be lowo nibe ko ni l lai fara gbegba ofun.

Iroyin fi towa leti pe wahala be sile laarin awon iko alamojuto ibudoko atawon ontaja kan lana, leyi to se okunfa akolu awon eeyan ati dukia lagbegbe Iwo Road.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *