Awako yoowu to ba gba opopona ti ko to lopopna olopo meji nipinle Oyo yoo sanwo itanran egberun lona aadota naira tabi ko padanu oko re, tabi alupupu re.

Alaga ajo to n se kokari igbokegbodo oju popo nipinle Oyo, OYRTMA, Oloye Akin Fagbemi lo laago ikilo yi lasiko to n baa won akoroyin soro nile ijoba ipinle Oyo to wa ni Agodi, ilu Ibadan.

Oloye Fagbemi salaye edun okan re, lori ijamba to n sele loju popo to n fojoojumo peleke si leyi to so pe o n waye nipase ki awako gba ona ti kii se tie, paapaa julo nilu Ibadan.

Oga agba ajo OYRTMA salaye wi pe gbogbo awon logaloga ajo naa lelekunjekun kaakiri ijoba ibile metalelogbon to wa nipinle yi ni won ti fun lase ati gbese le awako tabi okada pelu keke elese meta to ba tapa ofin naa.

Oloye Fagbemi salaye wipe ofin eto irinna ipinle Oyo fodun 2009 ni won ti se atunse re, ko lee ba oju ojo agbaye mu nipa ati le fiya to ye je eni to bat a pa si ofin naa.

 Adebisi/Salawudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *