Gomina Ipinle Oyo, Onimo ero Seyi Makinde ti soo di mimo wi pe ijoba re ti n sapa lati fi ri daju pe idagbasoke to nitumo jeyo nidi igbiyanju ati wagbo dekun fun eto aabo to mehe nipinle Oyo.

O sipaya oro yi lasiko ti awon omo ile igbimo asofin ile yi ti won n soju ipinle Oyo ti won je omo egbe oselu PDP lo baa lalejo loofisi re nilu Ibadan.

Gomina Makinde salaye wipe ijoba re ko kaare lori amigboro eto aabo.

Gomina makinde ro awon omo ile asofin naa pe ki won maa se ipade pelu awon eeyan ekun idibo won loorekoore, ki adiinku lee ba eru to wa lorun ijoba ipinle.

Saaju ni, omo ile igbimo asofin agba to n soju ekun idibo Guusu Ipinle Oyo, Dokita Kola balogun, to soro loruko awon yoku ti kan saara si Gomina Makinde fun ilosiwaju lolokan o jokan to n mu ba ipinle Oyo.

Senator Balogun tun seleri wipe awon omo egbe oselu PDP to w anile asofin ile yi ko ni kaare ninu atileyin fun ijoba to wa lode nipinle Oyo.

Adebisi/Salawudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *