Oga Agba ajo Asobode nile yi, Ajagun fehinti Hameed Alli ti di ebi biwon se nse fayawo eroja epo robi lati ile yi lo s’awon orile ede miran ru bi ajo NNPC at eyiti on risi oro ero robi DPR ko se ntele awon ilana.

Ajagunfehinti Alli soro yi lasiko to nfesi si ibeere igbimo teekoto ile igbimo asofin apapo keji lori eto isuna.

O salaye wipe ajo NNPC si ngbe epo fawon ile epo to wa ni aala ile yi lodi si imonran ti ajo asobode fun won.

Oga ile ise asobode ni ajo DPR ni tie ntesiwaju lati fun awon eeyan niwe ase ati da ile epo sile lawon alaa ile yi leyiti o lodi si ofin to ni ile epo o gbodo si ni ibuso mewa si aala ile yi.

Alaga igbimo teekoto ile igbimo asofin apapo keji, Ogbeni James Faleke so wipe ajo NNPC ti fi to awon lati wipe o to ogbon million litre epo ni won nji gbe nile yi lojoojumo latipase iwa fayawo.

Oluwayemisi Owonikoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *