Ìjọba àpapọ̀ ti sọ́ọ̀ di mímọ̀ wípé òun yóò pese ọ̀rọ tó ń ka iná ọba táà mọ̀ sí prepaid meter, bíì milliọnu mẹ́rin fáwọn ọmọ ilẹ̀ yí léyi tíì se ibi keji àkànse ètò meter pínpín jákèjádò ilẹ̀ yí.

Àtẹ̀jáde tí olùbádàmọ̀ràn pàtàkì fún àarẹ lórí ìpèsè ǹnkan amáyédẹrùn, ọ̀gbẹ́ni Ahmed Zakari fi síta sọ́ọ̀di mímọ̀ wí pé ètò gbogbo ti parí lórí ìgbésẹ̀ náà.

Ọgbẹni Zakari tẹnumọ pé, ìgbà náà yóò mú àdúnkù bá kíkó owó iná lọ́nà àitọ́ èyí táwọn ilésẹ́ tó ń pèsè iná ọba máà n kọ fún aráàlu, léyi tí yóò le jẹ́ káràalú máà san iye owó iná tí wọ́n bá lò ní pàtó.

Gẹ́gẹ́ bó se wí, àwọn iléesẹ́ tuntun kan ti wà nílu Èkó àti ìpínlẹ̀ Kaduna tí wọn ń pèsè ẹ̀rọ tón ka iná ọba, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ńse àtúnse àwọn ẹ̀rọ meter kan tí ọjọ́ ti lọ lórí wọn.

Alamu/Salaudeen.

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *