News Yoruba

Àjọ NBC, Sèlérí Àmójútó Tó Péye Fáwọn Iléèsẹ́ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́

Ó se pàtàkì fáwọn agbóhùnsáfẹ́fẹ́ láti ní ìmọ̀ kíkún wípé isẹ́ tí wọ́n yàn láàyo.

Torí bíì èyí, ó pọndandan fún wọn láti máà tẹ̀lé ìlànà àti òfin tó de isẹ́ náà.

Èyí ni èrò olùdarí àjọ tó ń se kòkárí àwọn iléèsẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórílẹ̀èdè yí, ẹkùn gúùsù ìwọ̀orùn, ọ̀gbẹ́ni Raphael Akpan lásìkò tón kópa lórí ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò níléèsẹ́ wa premier f.m lédè gẹ́ẹ̀sì táà pè ní THE STAGE.

Ọgbẹni Akpan sàlàyé wípé ọ̀pọ̀ iléésẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ló jẹ́ wí pé ètò tí kò pójú owó ni wọ́n máà ńgbé jáde fáràalú, pàtàkì jùlọ tó máà ń túnmọ̀ èdè gẹ́ẹ̀sì sí èdè abínibí.

Ọgbẹni Akpan tànmọ́lẹ̀ sí èrò àwọn èèyàn kan tí wọ́n sọ pé iléèsẹ́ náà máà ń ka àwọn iléèsẹ́ agbóhùsáfẹ́fẹ́ lápá kò láti sọ ohun tó yẹ, ó sàlàyé wípé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá bí kò se wípé wọn ń se atọ́nà fún wọn láti máà tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀.

Ó wá sọ àsọdájú pé àjọ rl yóò tẹ̀síwájú nínú ojúse àti ríì pé ohun tó tọ́, tó yẹ laráàlu ń gbọ́ lórí àwọn ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́.

Daramọla/Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *