News Yoruba

Gomina Makinde Beere Fun Iranwo Ile Ise Omo Ologun Lori Oro Aabo

Gomina Seyi Makinde tipinle Oyo ti beere fun atileyin ile ise omo ologun ile yi lawon enu aala Ipinle Oyo lati lee jeki Alafia ati aabo fese rinle.

Gomina Makinde soro yi lasikko ti olori awon omo ologun ile yi, Ogagun Farouq Yahaya sabewo si lara abewo enu ise re si ekun keji ile ise omoologun to wa ni Bareki Odogbo l’Ojoo nilu Ibadan.

Niigbeti o nfidi re mule pe looto ni gbun-gbun-gbun nwa laarin awon eeya ile yi, Gomina Makinde gboriyin fun ile ise omo ologun fun isapa re nidi gbigbogunti awon ipenija oro aabo tile yi nkoju.

Gomina wa jeje wipe ijoba ti oun nle waju re yio ma tesiwaju lati ko ipa tire nidi gbigbaruku ti ile ise omo ologun lati lee daabobo ile yi.

Saaju ni olori awon omo ologun ile yi, ogagun Farouq Yahaya ti mo riri Gomina Makinde fun iranlowo re fun ekun keji ile ise omo ologun ile yi.

Makinde/Owonikoko

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *