Ijoba apapo ti salaye igbaradi won lori itesiwaju ninu ajosepo to danmoran pelu orileede South Africa fun agbekale eto ti yoo mu agbeya ba orileede mejeeji.
Alakoso oro odo ati ere idaraya nile yi Ogbeni Sunday Dare lo sipaya oro yi lofiisi re nilu Abuja lasiko to ngbalejo Asoju Ijoba ile South Africa lorileede yi, Ogbeni Thamsanga Mseleka to se abewo sodo re.
Ogbeni Dare salaye wipe orileede mejeeji lo lee pese ise fawon odo lagbo ere idaraya ati eka eto eko pelu imo ayelujara to fi mo oro asa (culture) lona tiidagbasoke yio fi be ero amuludun ati oro aje won.
Ninu oro tie, Asoju Ijoba ile South Africa nile Nigeria Ogbeni Thamsanga Mseleka salaye wipe, oun gunle abewo naa lati salaye fun alakoso nipa igbaradi orileede re lori agbekale igbese ti yoo mu eto ajosepo lassrin ile Nigeria ati South Africa tunbo gbopo sin.
Net/ Salaudeen


