News Yoruba

Onimo Eto Ilera Pe Fun Ayewo Ilera Saaju Ere Idaraya

Won ti gba awon omo ile Nigeria nimoran pe ki won maa mo ipo ti ilera won wa saaju ti won to gunle ere idaraya ni sise.

Ogo agba leka ti won ti n se iwosan ara lai lo egbogi (physiotherapy) nile ekose imo isegun oyinbo, UCH, Ibadan, Dokita Ogundamen Obumneke lo soro iyanju yi lasiko to n kopa lori eto Straight Talk lede Geesi nileese wa Premier FM.

Dokita Obumneke, eni to kesi awon to n se idasile ibudo ere idaraya pe ki won maa rii daju pe won gba onimo ilera sibudo won, bee lo tun salaye Pataki ayewo ilera lati mo irufe ere idaraye to ye ti won maa se.

O tun pe fun eto ipolongo nipa Pataki ilera lai lo egbogi pelu agbega ipese eto isuna fun eka naa.

Kehinde/Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *