News Yoruba

Won ti gba awon omo ile Nigeria nimoran pe ki won maa mo ipo ti ilera won wa saaju ti won to gunle ere idaraya ni sise.

Ogo agba leka ti won ti n se iwosan ara lai lo egbogi (physiotherapy) nile ekose imo isegun oyinbo, UCH, Ibadan, Dokita Ogundamen Obumneke lo soro iyanju yi lasiko to n kopa lori eto Straight Talk lede Geesi nileese wa Premier FM.

Dokita Obumneke, eni to kesi awon to n se idasile ibudo ere idaraya pe ki won maa rii daju pe won gba onimo ilera sibudo won, bee lo tun salaye Pataki ayewo ilera lati mo irufe ere idaraye to ye ti won maa se.

O tun pe fun eto ipolongo nipa Pataki ilera lai lo egbogi pelu agbega ipese eto isuna fun eka naa.

Kehinde/Salaudeen

Yoruba

Siwaju sii, ijoba apapo yoo se idasile ero to nseranwo feemi eda, oxygen, ni gbogbo ipinle towa lorileede yi, gege bi ara ona lati koju wahala ti ero naa nfa lawon ibudo ifiniwo at itoju.

Alaga, iko amuseya ijoba apapo farun covid-19 ptf, titu se akowe agba sijoba apapo, Ogbeni Boss Muustapha, so eyi nilu Abuja, nibi abo iko naa.

O salaye pe, bawon eeyan ba se n lugbadi aarun ohun, be lawon eeyan o se maa po ni awon ibudo itoju to si le mu ko seese kawon ibudo odun kun akunfaya.

Alaga ajo ptf, salaye pea won igbese ohun ti n je gbigbe lati satileyin fawon liana abo covid-19 to w anile tele lati fese abo mule dain-dain.

 Idogbe/Net