Yoruba

Oludari Agba Ajo NAFDAC Nfe Kawon Araalu Maa Setoju Ounje Won Nitori Ewu Eroja Chemical

Ajo to n risi ipenija ohun tenu nje ati mimu pelu egboogi lorileede yi, NAFDAC, ti sekilo fawon omo ile Nigeria pe ki won yago fun kiko ounje pamo sinu ile pelu lilo ike ti won lo fun eroja egboogi taa mo si chemical leyi to je pe o lewu fun ilera won.

Oludari agba ajo NAFDAC, Ojogbon Mojisola Adeyeye lo sekilo yi lasiko ero ipolongo kan to waye nile Onitsha ipinle Anambra.

Ojogbon Adeyeye salaye wipe, irufe awon ike ti won fi n ko inkan pamo yi lo je pea won ileese kan fig be egboogi taa mo si chemical ati wi pe ko si iye igba teeyan fi le fo awon ike yi ti oro eroja chemical to wa ninu re yoo mo to si lee se ipalara fomo eniyan.

Oludari agba naa, eni ti oludari leka igbelewon eroja chemical ati ise iwadi fun ajo naa, Arabinrin Ngozi Onuora soju fun salaye wipe o lewu lati lo oko to won fi ngbe eroja kerosene fun gbigbe ororo epa tawon eeyan yoo lo.

Ojogbon Adeyeye wa rawo ebe, sawon oba alaye pe ki won lo ipo won fun ajo NAFDAC lawon agbegbe esekuku, ki ajo naa le se aseyori nipa ati rii daju pe awujo mo lowo ilokilo egboogi atawon inkan ilo to lee se omo eeyan ni ijamba.

Babatunde Salaudeen/Aminat Ajibike

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *