Gomina Banki Apapo ile yi tele titun se oludije l’abe asia-egbe oselu, All Progressive Grand Alliance, APGA, Ojogbon Chukwuma Soludo to jawe olubori ninu eto idibo Gomina t’ipinle Anambra lohun fi sori awon olopa meta ti won pa leyin oun lasiko ipolongo ibo.

Awon agbebon lo kolu iko re nibi ipade agbegbe eyiti o waye nilu abinibi re Isuofia n’ijoba ibile Aguata n’ipinle Anambra.

Ni kutukutu owuro oni ni ajo eleto idibo ile yi INEC ti kede Ojogbon Soludo gegebi eniti o jawe olubori ninu eto idibo to waye.

Oludari eto idibo naa, Ojogbon Florence Obi kede esi ibo naa lofisi ajo INEC to wa l’Akwa nipinle Anambra.

Ojogbon Soludo eniti o je Gomina Banki apapo ile yi laarin odun 2004 si 2009 ni won kede ijawe olubori re leyin ti won di ibo yoku nijoba ibile Ihiala eyiti won o di ni ojo kefa osun taa wa yi.

Oluwayemisi Owonikoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *