Pẹ̀lú bí ayẹyẹ ọdún kérésì se kún fún àkókò ìfifúnni, wọn ti rọ àwọn tọ́lọrun sẹ́giọlà fún láwùjọ àtàwọn onínú dídùn ọlọ́rẹ nílẹ̀ Nàijírìa pé kí wọ́n máà se ìrántí àwọn tó kudiẹ̀ káàto fún láwùjọ nípa ǹkan amáyédẹrùn fún wọn lásìkò pọ́pọ́sìnsìn ọdún yi.

Ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, arábìnrin Taminonimini Makinde ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò àpèjẹ ọdún fáwọn èwe nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Arábìnrin Makinde tẹnumọpé, kò sí iye tó kéré tí kò ní ní ipa.

Ìyàwó Gómìnà wá késí gbogbo ọmọ ill yí pé kí wọ́n yàgò fún ìwà ìmọtaraẹni nìkan, tó sì tẹnumọ́ ìdí tó fi yẹ kéèyan se ọdún ní ìwọ̀ntunwọsì.

Lára ohun tó wáyé níbi ètò náà ní bi babakérésì se ń fún àwọn ọmọdé tó wà láti gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ tó wà nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ lẹ́bùn ọdún.

Olarinde / Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *