Ẹgbẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì nílẹ̀ yí, ASUU, ti sẹ́wẹ́lé ìyansẹ́lódì tí wọ́n ń gbèrò rẹ̀ nípa bó se jẹ́ pé ìfikùnlukùn ti ń lọ lórí ohun tí wọ́n ń bèèrè fún.

Ẹgbẹ́ olùkọ́ náà ló tún kéde ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìgbáradì fún ìyansẹ́lódì náà lóse tó kọjá ló jẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé wọn kò tíì pèsè ohun tí wọ́n ń bèrè fún.

Nínú àtẹ̀jáde tí àarẹ ẹgbẹ́ ASUU nílẹ̀ yí, ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Osedeke fi síta ni wọ́n ti kéde pé ìdúró ò sí ìbẹ̀rl òsí láàrin ẹgbẹ́ náà àti ìjọba lórí ètò ìgbáyégbádùn àwọn olùkọ́, pẹ̀lú àlàyé wípé ìjọba àpapọ̀ ti kùnà láti se àmúsẹ ohun tí wọ́n jọ fẹnukò lé lórí lọ́dún 2009.

Ẹgbẹ́ ASUU sàlàyé wípé ìjọba àpapọ̀ kùnà láti se àtúngbéyẹ̀wò àdéhùn ọdún 2009 àti pé gbogbo ìgbésẹ̀ tó bá jẹ́ gbígbé lákokò yí ni yóò sọ ìlànà tẹ́gbẹ́ ASUU yóò tẹ̀lé lákokò yí.

Net / Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *