Egbe awon oluko ile eko giga fasiti nile yi, ASUU ti soo di mimo pe ajo to n seto idanwo ati wole sile eko giga (JAMB) lo leto lati maa set igbaniwole sawon ile eko giga.

Ninu atejade, eyi ti aare egbe ASUU, Ojogbon Emmanuel Osodeke fi sita lo ti salaye wipe igbese ajo JAMB lati maa seto liana igbani wole sile eko giga lo je ikoja aaye si Ominira ile eko giga fasiti.

O tenumo pe, ajo JAMB ko lagbara lato seto odiwon fun eni to koju osunwon lati wole sile eko giga fasiti tabi fagile illana eto eko nile eko giga fasiti.

Ojogbon Osodeke tun se afikun e wipe ojuse igbimo alase ile eko giga fasiti kookan ni lati se agbekale liana eto eko pelu liana igbaniwole sile eko giga fasiti won yala imo ijinle akoko tabi imo ijinle keji.

Fadahunsi/Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *