Ile Igbimo Asofin ile Nigeria ti fun awon ijoba ibile nile yi lominira eto enawo jakejado ile Nigeria pelu bo se pari agbeyewo ofin odun 1999.

Awon asofin ile igbimo asofin mejeeji ni won dibo lori aba ofin mejidinlaadorin pelu bi won se foowo si awon kan ti won si satako sawon min.

Ninu ibo won ni won ti fowosi ofin to n faaye gba oludije ti o si labe asia egbe oselu ti won sit un fowosi bi won se gbe ofisi agbejoro agba ile yi kuro nile ise eto idajo.

Bankan naa lawon asofin ohun dibo tako kawon to n dari ile igbimo asofin maa gba owo ifehinti ti won si tun tako aba ofin ti won gbe kale lori sise igbelaruge didasi eto oselu awon obinrin ile Nigeria.

Nigba to nsoro, aya igbakeji aare ileyi, arabinrin Dolapo Osinbajo tohun naa wa ni bi ijoko ile, salaye pe bi won se tako ofin to ro mo awon obinrin kiise ipe fun fifaaye gba awon obinrin ile yi.

 Blessing Okareh/Ayodele Olaopa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *