Agbẹjọ́rò kan, ọ̀mọ̀wé Kazeem Olaniyan ti gbàwọn  ọmọ ilé- ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ níyànjú láti tọwọ́ òfin tóníse pẹ̀lú káwọn asojú kan bo somun bọnú àtúnse ìwé òfin tónlọ lọ́wọ́.

Ọmọwe Ọlaniyan tótún jẹ́ olúkọ̀ lẹ́ka tíwọ́n tin kọ́ nípa ìmọ̀ òfin nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìbàdàn ló gbọ̀rọ̀ àmọ̀ràn yíì kalẹ̀ lákokò tó ń kópa lórí ètò ilé-isẹ́ Radio Nigeria kan lédè gẹ́ẹ̀sì, tamọ̀sí Straight Talk, níkànì Premier F.M 93.5.

Ó sàlàyé pé, àgbékalẹ̀ irúfẹ́ òfin bẹ́ẹ̀ sepàtàkì nítorí báwọn Gómìnà kan se ńkúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú tó fìbò wọn gbéwọn dépò, nítorí bí òfin se dákk lórí ohun tó tako ìgbésẹ̀ wọn ọhun.

Ọmọwe Ọlaniyan tún fikun pé, ìbó tó yan Gómìnà yóòwù, àtinú ẹgbẹ́ òsèlú rẹ̀ lótiwá, nítorí náà níkò fi bójumu fúnrúfẹ́ Gómìnà bẹ́ẹ̀ láti kúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú rẹ̀ bọ́sínú omin-in.

Kò sài tún sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, ìgbésẹ̀ àwọn asòfin ìpińlẹ̀ Eboyin tíwọ́n kúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú wọn pẹ̀lú Gómìnà David Umahi lòdì sófin, tíwọ́n si n fọwọ́ pa idà òfin lójú.

Kehinde/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *