Ijoba ipinle Ogun ti gbe awon ile mejilelogbon to wa ni Isheri nijoba ibile Ifo nipinle naa tipa, nitori pe won tapa si oniruru ofin to romo ile kiko.

Alakoso to wa fun eto ile ati idagbasoke igberiko, Ogbeni Olatunji Odunlami, lo soro yi di mimo lasiko to n baa won akoroyin soro nilu Abeokuta, to kasi pe opo ninu awon ile naa ni won ko gba ase lati ko.

Ogbeni Odunlami tenumo pe gbigba ase lati bere ile kiko ki se on to ye keeyan fi fale tabi mu sere, o tokasi pe isejoba to wa lode nipinle Ogun ni o fe sise ri daju pe abo to peye wa nipinle ohun, kawon eeyan le dokowo layika to rorun.

Alakoso naa wa gba awon to nile niyanju lati yago fun titapa si ofin ijoba.

Amugbalegbe Pataki si Gomina lori ato ilu ati idagbasoke igberiko, Ogbeni Tunde Ohegbewesa, naa bere atilehin awon to ni ile, ki won le fese abo to peye layika fun awon eeyan ipinle Ogun mule.

Folarin/Okareh/Afonja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *