Ìgbìmọ̀ tó gajùlọ, tón rísí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn Islam lórílẹ̀ èdè Nàijírìa (NSCIA) ti rọ àwọn Mùsùlùmí òdodo láti fojúsọ́nà fún rírí osù, kété tí òrùn bá wọ̀ lóni.

Gẹ́gẹ́bí àtẹ̀jáde èyí tí olùdarí ìgbìmọ̀ tón sàkóso NSCIA, Àlhájì Zubairu Usman-Ugwu àti àarẹ ìgbìmọ̀ ọ̀hún, ti tún se Sultan tìlú Sokoto, Muhammad Sa’ad Abubakar ni yo kéde ọ̀la gẹ́gẹ́bí ọjọ́ àkọ́kọ́ osù Ramadan 1443, bí Mùsùlùmí òdodo bá fojú gánní osù.

Àtẹ̀jáde náà tọ́kasi pé, àmọ́ bí wọ́n kò fojú gánní osù lóni ọjọ́àikú tíse ọjọ́ kẹta osù kẹrin ọdún tawàyí ni yo jẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ osù Ramadan 1443 AH.

Àtẹ̀jáde shún wá rọ àwọn Mùsùlumí òdodo láti fi tó àwọn ìgbìmọ̀ alásẹ tón rísí, rírí òsùpá láti kété tí wọ́n bá ti fojú gánní rẹ̀.

Fadahunsi/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *