Òjò alágbára tó rọ̀ nílu’bàdàn lána òde yi ti ba àwọn ilégbe iléwe tófimọ́ òpó iná jẹ́.

Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria tó tọpinpin ìsẹ̀lẹ̀ náà, jábọ̀ pé òrùlé àwọn ilégbe kan lágbugbò Agbowó àti orogún ni ìjì ọ̀hún gbé lọ.

Yàtọ̀ fún àwọn ìgì tó wọ́lu ojú òpópónà, àwọn irinsẹ́ tón mú iná wọlé ilésẹ́ IBEDC náà ló tún di bíbàjẹ́.

Ilésẹ́ Radio Nigeria tún wóòye pé àwọn ilé ńmú ilé ìwé orogún Girammer school ni óbàjẹ́ kọjála.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú olùgbé méjì ní orogún, ọ̀gbẹ́ni Sakiru Iyanda àti ọ̀gbẹ́ni Kazeem Ọladẹjọ sọ wípé òjò náà ti ba ọ̀pọ̀ ǹkan jk ládugbò, tí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ síjọba láti sètò ìrànwọ́ fáwọn tó ní ilé tí òjò bàjẹ́, ní kìakìa.

Famakin/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *