Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí níì gbé àwọn aláàjì láti orílẹ̀ èdè Saudi Arabia padà wa sílẹ̀.

Báàlù pẹ̀lú nọ́mbà ìmínimọ̀ xy7002 tó gbé àwọn aláàjì tó lé ní irinwó láti olú ìlú ilẹ̀ yí lọ gbéra kúrò ní pápá òfurufú ọba Abdulazeez tó wà ní Jeddah wá sí pápákọ̀ Nnamdi Azikwe nílẹ̀ yí.

Alága àjọ alaaji ilẹ̀ yí NAHCON, Àlhájì Zikrullah Hassan fàmì ìdánilójú yi hàn pé gbígbé àwọn alaaji wálé ni yi wáyé létò létò.

Àwọn tó wá láti ìpínlẹ̀ Borno àti Ọsun ni ìrètí wà pípé wọn yio gbéra kúrò ní orílẹ̀ èdè Saudi Arabia lóni nígbàtí àwọn ọmọ ilẹ̀ yí tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náà yio bẹ̀rẹ̀ wíwálé ní sísẹ̀ ǹtẹ̀lé lẹ́yìn tí wọ́n ti parí isẹ́ hajj wọn.

Ridwan Fasasi/Yemisi Owonokoko  

 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *