Àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ yí, INEC, ti pín àwọn ohun èèlò ìdìbò sáwọn ìjọba ìbílẹ̀ ọgbọ̀n ní ìpalẹ̀mọ́ fún ètò ìdìbò sípò Gómìnà tí yio wáyé nípinlẹ̀ Ọsun lọ́la.

Pínpín àwọn ohun èèlò ìdìbò ọ̀hún ló wáyé ní ọ́fìsì INEC, tó wà l’ósogbo níbití àwọn asájú ẹgbẹ́ òsèlú, àwọn oníròyìn àti ònwòye ètò ìdìbò péjú pésẹ̀ si.

Ọga àgbà àjọ INEC, nípinlẹ̀ Ọsun, ọ̀jọ̀gbọ́n Abdulganiyu Raji ni wọ́n kó àwọn ohun èèlò ètò ìdìbò lọ sáwọn ófìsì INEC, tó wà láwọn ìjọba ìbílẹ̀ pẹ̀lú ààbò tó péye.

Gẹ́gẹ́bí ọ́jọ́gbọ̀n Raji se sọ, àwọn ọ́gá àjọ INEC, àpapọ̀ márun àti àwọn lọ́galóga méjìlá láti àwọn ìpínlẹ̀ min ni wọ́n ti wà lárawọ́tó láti sàmójútó ètò ìdìbò láwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n yàn fún wọn.

Ọjọgbọn Raji sàla[yé wípé àwọn ìwé ìdìbò àti ibití wọ́n yio sàkọsílẹ̀ rẹ̀ si ni wọ́n se lára ọ̀tọ̀ fún ìjọba ìbílẹ̀ kànkan àti ibùdó, tó w;a fikun wípé àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tí òun ó ba buwọ́lù ni wọn ni gba wọlé bíì ojúlówó.

Net/Yemisi Owonikoko

 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *