News Yoruba

Àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó nílẹ̀ Náigírìa ti sọpé dandan ni fífi sára ọkọ̀ ohun sísàmúlò ẹ̀rọ asòdinwọ̀n eré sísá fáwọn awakọ̀ kólè mú àdínkùn bá eré àsápajúdé lójú pópó.

Ọga àgbà àjọ náà fún ìpínlẹ̀ Ògùn, ọ̀gbẹ́ni Ahmed umar ló yọjú ọ̀rọ̀ náà síta lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn nílu Ọta.

Ọgbẹni Umar wá rọ àwọn onímọ̀ tó láti ri dájú pé wọ́n sọ ẹrọ ohun gẹ́gẹ́bí ǹkan tó se kókó kólè mú àdínkù bá eré sísá.

Ó sàlàyé pé àjọ FRSC, ti mú ọrọ náà lọ́kunkúndùn kítẹ̀síwájú le máà ba .

Bákanà náà lótún sọ pàtàkì ẹ̀rọ ọhun fáwọn ọkọ̀ ẹrun ńla ńla, àtàwọn awàkọ̀ bọ́sí ero.

Ọgbẹni Umar wá rọ àwọn awakọ̀ láti lọ sórí ikanni orí ẹ̀rọ ayélujára àjọ náà láti darapọ̀ mọ́ alámojútó ereọ ohun láwọn ìpínlẹ̀ nítorípé ìpínlẹ̀ kọ́ọ̀kan lóni alámojútó lọtọọtọ.

Ayọade/Ọlaọpa

Yoruba

Àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó, nílẹ̀ yíì, FRSC ẹ̀ka tìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti gùnlé ìparáarọ tí wọn pè orúkọ rẹ̀ ní operation Zero’’ láti fi kojú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ láwọn òpópónà ńlá ńlá.

Ọga àgbà àjọ náà nípinlẹ̀ yí, Arábìnrin Uche Chukwurah ní ìgbésẹ̀ náà se pàtàkì láti léè jẹ́kí èróngbà wọn láti máse sàkọsílẹ̀ ìjànbá ọkọ̀ lásìkò pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún wá sí ìmúsẹ.

Arábìnrin Chukwurah ní àjọ ọ̀hún ti kó àwọn òsìsẹ́ rẹ̀ tótó ẹgbẹ̀sán síta tí wọn sì tún kó ọkọ̀ ìparaaro mọ́kànlélógún, ọkọ̀ ìgbé aláisan kan àti ọkọ̀ tí wọ́n fi ńfa ọkọ̀ kan síta.

Ó fikun wípé wọ́n yio tún tẹra mọ́ ìpolongo wọn láwọn ibùdó kọ̀ láti ríì wípé àwọn èeyàn tẹ̀lé ìlànà ìtakété síra ẹni, lílo ìbómú àti fífi òróró apakòkòrò sanitizer pawọ́ láti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19.

Arábìnrin Chukwurah wá kílọ̀ fáwọn awakọ̀ láti tẹ̀lé gbogbo àlàkalẹ̀ tàbí kí wọ́n fojú winà òfin.

Rasheedah Makinde/Fọlakẹmi Wojuade