Àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó, nílẹ̀ yíì, FRSC ẹ̀ka tìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti gùnlé ìparáarọ tí wọn pè orúkọ rẹ̀ ní operation Zero’’ láti fi kojú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ láwọn òpópónà ńlá ńlá.

Ọga àgbà àjọ náà nípinlẹ̀ yí, Arábìnrin Uche Chukwurah ní ìgbésẹ̀ náà se pàtàkì láti léè jẹ́kí èróngbà wọn láti máse sàkọsílẹ̀ ìjànbá ọkọ̀ lásìkò pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún wá sí ìmúsẹ.

Arábìnrin Chukwurah ní àjọ ọ̀hún ti kó àwọn òsìsẹ́ rẹ̀ tótó ẹgbẹ̀sán síta tí wọn sì tún kó ọkọ̀ ìparaaro mọ́kànlélógún, ọkọ̀ ìgbé aláisan kan àti ọkọ̀ tí wọ́n fi ńfa ọkọ̀ kan síta.

Ó fikun wípé wọ́n yio tún tẹra mọ́ ìpolongo wọn láwọn ibùdó kọ̀ láti ríì wípé àwọn èeyàn tẹ̀lé ìlànà ìtakété síra ẹni, lílo ìbómú àti fífi òróró apakòkòrò sanitizer pawọ́ láti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19.

Arábìnrin Chukwurah wá kílọ̀ fáwọn awakọ̀ láti tẹ̀lé gbogbo àlàkalẹ̀ tàbí kí wọ́n fojú winà òfin.

Rasheedah Makinde/Fọlakẹmi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *