Yoruba

Iyawo Gomina Ipinle Oyo, Arabinrin Tamunominimi Makinde ti kesi awon omo ile Nigeria pe ki won dide atileyin fawon obinrin to lugbadi ijamba lasiko abe dida fomobirin.

Arabinrin Makinde soro imoran yi lasiko eto ayajo fifopin si abe dida fomobinrin fun todun yi.

Iyawo Gomina, eni ti alakoso akanse ise nipinle Oyo, Arabinrin Fausat Sanni soju fun tenumo pe ti atileyin ba n wa fun awon obinrin to ba lugbadi isoro lasiko abe dida, eyi yoo tun maa je ona itura fun ru awon ibisi ati onka omoniyan, Dokita Oladosu Ojengbede salaye wipe ipinle Oyo lo wa ni ipo keta awon ipinle to ni akosile isoro abe dida fun omobinrin o salaye wi pe, ipolongo atigbadegba to n lo lee mu adinku ba asa naa.

Alamojuto eto abe dida fomobinrin nipinle Oyo, Arabinrin Balqis Olawonyin naa salaye wipe awon Oloola to n dabe lona ibile lo ti n se ise papo pelu won lati fopin si asa naa.

Baba isale egbe awon oloola nile yi, Oloye Abiola Ogundokun naa salaye wi pe abe dida fomobinrin lewu ju anfani lo, o wa ro won pe ki won jawon ninu asa naa.

Awon to kopa nibi eto naa lo korajo latinu egbe bi PFN, FOMWAN, NASFAT, ati egbe awon agbebi ibile.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Gẹ́gẹ́bí ara ọ̀nà láti fòpin sí ètò àbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ ìbàràpá, adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ti gbé alùpùpù mẹdogun tuntun fáwọn ẹ̀sọ́ alábo tójẹ́ ọmọbíbí ilẹ̀ ìbàràpá.

Nígbà tón gbé àwọn alùpùpù náà fáwọn olórí agbègbè àti àwọn asíwájú ẹ̀sọ́ alábo lágbègbè nílesẹ́ ọlọ́pa tówà nílu Èrúwà, ọ̀gbẹ́ni Ogundoyin sọpé, ìgbésẹ̀ náà lówáyé láti mú àgbéga bá lílọ bíbọ̀ àwọn òsìsẹ́ alábo àmọ̀tẹ́kùn, OPC, àwọn ọdẹ tófimọ́ ikọ̀ vigilantee, láti mú àmú gbòrò dé bá isẹ́ wọn.

Nígbà tón fèsì, ọ̀gágba ilésẹ́ ọlọ́pa Èrúwà, ọ̀gbẹ́ni Peter Ugochucwu fi ẹ̀mí ìmore hàn sí olùdarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin, fún àtìlẹ́yìn tó se fún ẹ̀sọ́ alábo gbogbo.

Nígbà tón rọ àwọn èyàn láti túnbọ̀ sátìlẹyìn fún ilésẹ́ ọlọ́pa náà lọ́wọ́, sọwọ́ sí wọn, ọ̀gbẹ́ni Ugochuckwu wá fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé, ètò àbò yo tunbọ gbèrú si láwọn agbègbè náà.

Bákanà, alága, ìgbìmọ̀ àwọn olórí lágbègbè náà olooye Joseph Peluọla fi ìdùnú hàn lórí ìgbésẹ̀ olùdarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípa dídahun si ìbere àwọn èyàn lójú ọjọ́.

Láfẹ̀mọ̀júmọ́ ọjọ́ àikú Sunday tó kọjá, ni ìkọlù kan wáyé ní Ìgàngàn, lágbègbè ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Ìbàràpá nínú èyí tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ti sọnù tọ́kẹ àimọye dukia sì jóná tófimọ́ àfin Ashigangan tìlú Ìgàngàn.

Folakemi Wojuade