Yoruba

Ijoba apapo ti so pe ko si ooto ninu iroyin to n ja rohinrohin pe aarun romolapa romolese ti be sile lawon ipinle kookan.

Ijoba fowo idaniloju re soya pe ko ti si isele aarun naa tuntun nile yi lati odun 2016.

Ogaagba eto idagbasoke ilera alabode, Dokita Faisal Shuaib eni to ni ko si ooto pea run na tun ti seriyo, sope ni loolo yi ile yi ni, awon to ni, to fe to irinwo niye yika ipinle meta din logbon ati oluulu ile yi Abuja.

Dokital Shuaib wa fi da awon eeyan ile yi loju pe, won yoo tesiwaju lati ma lo yika ile yi, ti ipolongo yo si tesiwaju pelu awon torokan lati le dekun kiko arun wole lati orileede okeere.

O wa tenumo Pataki, ki awon obu atalagbato ma setoju awon omo won dunju, lai yo gbigba abere ajesara sile, eyito n dena awon arun.

Ololade Afonja

News Yoruba

Laifi ti iroyin to n ja rain-rain pe aisan ko to farape romolapa romolese ti ja lawon apa ibikan nile yii se akosile to sope kosi aisan romolapa romolese mo nile yi si wa digbi.

Oga Agba Ajo to nrisi ile-iwosan alabode nile yii, Dokita Faisal Shuaib so fawon oniroyin nilu Abuja wipe, ijoba tiko abere ajesara faisan romolapa tomolese jade fawon omode tojo ori won wa labe odun marun lati dena aisan tofarape romolape romolese lawon ipinle metalelogun.

O ni lati igbati won ti kede wipe ile yi ti jajabo lowo aisan naa, ko ti si akosile wipe enikeni nii arun romolapa-romolese nile yi.

Orileede Nigeria atawon ekun ile adulawo ni won ti fun ni iwe eri wipe won ti we yan kain kain lowo arun romolapa-romolese lojo karundinlogbon osu kejo odun 2020.

Net/ Idogbe