Yoruba

Àjọ àbò ara ẹni láàbò ìlú, NSCDC, ti fàwọn òsìsẹ́ àjọ náà ẹgbẹ̀rúnméjìlélẹ́gbẹ̀rin sọwọ́, fún ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí yóò wáyé lọ́jọ́ àbámẹ̀ta ọjọ́ kejìlélógún osù larun ọdún yíì nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Ọga àgbà àjọ NSCDC nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ogbẹ́ni Iskilu Akinsanya sọ èyí lólú-ìlú ilésẹ́ náà, Agodi Ìbàdàn, lásìkò ìpàdé tóse po pẹ̀lú àwọn òsìsẹ́ àjọ náà nígbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àti ìjọba ìbílẹ̀ alábọ́dé márùndínlógójì tówà nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Ó ní, gbogbo àwọn òsìsẹ́ àjọ náà ni yóò wà lẹ́nu isẹ́ lọ̀jọ̀ ìdìbò ọ̀hún, ọ̀gbẹ́ni Akinsanya kò sài wá rọ àwọn òsìsẹ́ àjọ náà tí yóò sisẹ́ ni woodu ẹgbẹ̀rún mẹ́rin din-in diẹ àti ibùdó ìdìbò ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndín diẹ láti se ohun gbogbo níbamu pẹ̀lú ìlànà àjọ elétò ìdìbò ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ kíwọ́n sijẹ asojú rere fájọ NSCDC.

Bákanà ló tún rọ àwọn olórí agbègbè àtàwọn adarí ẹ̀sìn tófimọ́ ẹgbẹ́ àwọn baba onílẹ làti sèkìlọ̀ fáwọn èèyàn nídi síse ohun gbogbo tóníse pẹ̀lú ètò ìdìbò náà bótitọ́ àti bótiyẹ.

Bẹ́sìni ọ̀gbẹ́ni Akinsanya níì o se pàtàkì káwọn olùdìbò tẹ̀lé ìlànà àti ìgbésẹ̀ àabò covid 19, kíwọ̀n sì gbé ìwà ọmọluabi wọ̀, sáájú lákokò àti lẹ́yìn ìdìbò.

Ó wá fikun pé, níti ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì àwọn aráàlu léè pe sórí àwọn nomba ẹ̀rọ wonyi; 09070473188, 08058268164, 08077513995, 09055533303, àti 08160377637.

Idogbe   

Yoruba

Ajo eleto idibo ipinle Oyo, OYSIEC ti sun eto idibo ijoba ibile si ojo kejilelogun soun karun odun yi.

Alaga ajo OYSIEC, Oloye Isiaka Olagunju lo fi ikede naa sita lasiko abewo to se si ajo to n ti si idagbasoke awon agbe, OYSADEP, eyi to wa ni Moore Plantation, Apata, Ibadan.

Oloye Olagunju tenumo pe, o pondadan lati sun ojo idibo naa siwaju lati maa dun awon Musulumi to fe rinrin ajo lasiko odun itunu aawe ni eto won.

Alaga ajo OYSIEC tun toka sip e awon agbe se Pataki fun eto ipolongo ajo naa leyi to se okunfa abewo sodo won kadinku o lee ba akude to le fe way lasiko eto idibo ijoba ibile to n so.

O salaye wi pe won yio gbe ise oruko oludibo jade laipe, o wa ro awon ti kaadi idibo alalope won ba ti baje pe ki won toju iwe idanimo ile yi, tabi iwe ase iwako lati le fun won lanfaani ati kopa nibi idibo naa.

Ninu oro re, Alaga Ajo OYSADEP, Alhaji Salihu Imam gba awon araalu nimoran pe ki won tu yaapaa jade fun eto idibo to n bo naa lati yan eni to wuwon si joba ibile.

Salaudeen