Yoruba

O se Pataki ki ajosepo was laarin ijoba ni gbogbo eka ati ileese aladani lati mu ki amugbooro de ba nini anfani si eto ilera to koju owo.

Igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo lo soro yi lasiko to n siso loju ipade apero eto ilera alabode kan nilu Abuja.

Ojogbon Osinbajo tenumo pe ibasepo laarin ijoba nigbogbo eka, ni yoo wojutu si gbogbo ipenija to n suyo leka eto ilera alabode.

Ninu oro tie, alakoso feto isuna, Omowe Zainab Ahmed so pe ijoba apapo ni o fe ki eto ilera adojutofo kari gbogbo eeyan, papajulo awon to ku die kato fun.

                        Okareh/Afonja

News

Àjọ tó rísí ètò ìlera nípinll Èkó sọpé, ohun ti ńgbé ìgbésẹ̀ láti sàfikún àwọn olùgbé tóòtóò milliọnu mẹ́ta sínú ìlànà ètò ìlera adójútófo ti ìforúkọsílẹ̀ náà yóò sì wáyé lárin ọdún kan.

Alákoso àgbà fájọ ọ̀hún Dókítà Emmanuẹla Zamba, sọ èyí di mímọ̀ níbi ìpàdé ètò ìlanilọ́yẹ̀ àwọn èèyàn ẹsẹ kùkú àti ìgbésẹ̀ iforukọ sílẹ̀ tó wáyé nípinlẹ̀ náà.

Díkítà Zamba ẹnitó sàlàyé pé, ètò ìlanilọ́yẹ̀ àti iforukọ sílẹ̀ ọ̀hún sepàtàkì nítirípé ìlera lọrọ̀ àtọ́kasí.

Àwọn irinsẹ́ toye pe okolerugbaole méjì ló ti wan kanlẹ láti sètò iforukọ sílẹ̀ ná. Elizabeth Idogbe

Yoruba

Awon eeyan ipinle Oyo toleni egberun  lona  igba lo je anfani eto ilera ofe eyiti ilese eto ilera ipinle oyo ati ajosepo eto ilera ofe  omititun sagbekale re.

 Eto ohun eyi to bere ni ijoba ibile ila –oorun ibarapa nipinle oyo, lawon eeyan jnafani itoju ofe lori okojokan aisan bi, iba, eje riru, ipenija eyin aisan ayokele foju, ati bebelo.

 Nibi asekagba eto olojo letaelogun ohun, aya gomina ipinle Oyo, Arabinrin Tamunominnini Makinde ro awon eeyan lati mu eto ilera won lokunkundun.

 Arabirin Makinde sope eto ilera ofe ohun, fojusun mimu – agbega ba igbe aye Alafia ati eto oro –aye.

 Alakoso feto ilera nipinle Oyo, Dokita Basher Bello sodi mimo pe eto ohun , totide opo ijoba ibile ipinle Oyo yoo maa waye losu meta – meta.

 Meji ninu awon to je anfani eto naa, ogbeni asimiyu adekunle ati arabinrin toyin babalola gboriyin fun awon to se agbateru eto naa.

Idogbe