Yoruba

Awon elesin abalaye nipinle Oyo ti gbosuba fun, Gomina Ipinle Osun Ogbeni Gboyega Oyetola lori igbese kikede isinmi lenuse lati samin ayajo ojo isese nipinle.

Ninu atejade eyi ti alaga egbe awon elesin abalaye teka ipinle Oyo Ogbeni Adefabi Fadiran ati akowe, omowe Fakayode Fatunde fisita nilu Ibadan, tokasi pe Gomina ti fi emi igboye han, nipa sise atileyin fun asa ati ise Yoruba.

Atejade naa wa kesi awon omo egbe nipinle Oyo lati sajoyo odun Isese laisi gbungbun kan, ki won si gbadura fun Alafia ile Yourba, Orileede Nigeria, Ipinle Oyo ati agbegbe lapapo.

Ayajo odun Isese todun 2021 ni won nse ni gbogbo agbaye logunjo osu kejo, odoodun.

Ololade Afonja

Yoruba

Gomina ipinle Osun, Ogbeni Adegboyega Oyetola ti so di mimo pe ona kan soso tile yi fi lee wa ojutu is ipenija eto aabo ni pinpin agbara nilana ile ise olopa.

Gomina Oyetola soju oro yi lede nilu Abuja pelu alaye wipe awon ileese agbofinro ile yi lo je pe ojukan ni agbara won sodo si, leyi to jinna si esekuku lati fi pese eto aabo to ye fun ileyi.

Nigha to n lu ijba apapo logo enu lori idasile olopa agbegbe, o ta ka rip e igbese yi lo le tete so eso rere ti kii baa se ijoba apapo nikan lo ndari eto aabo.

Gomina naa salaye wi pe eto aabo, isejoba ati ifesemule idagbasoke eto oro aje lo ye ko tele ara won lati fi lee je ki orileede duro re.

Salaudeen